ONDO KINGDOM:ṢÈYÍ TI JAGUNMÓLÚ

ṢÈYÍ TI JAGUNMÓLÚ!

By Ayélabégàn Akínkúnmi Baba Awo.
Ọ̀kan gbóògì nínú ọmọ ẹgbẹ́ GSM ADVOCATES
Ìwọ̀ -oòrùn Ọ̀yọ́

ONDO KINGDOM:ṢÈYÍ TI JAGUNMÓLÚ!
ONDO KINGDOMṢÈYÍ TI JAGUNMÓLÚ

B’éwúrẹ́ bá kangídì a dòbúkọ,
Àgùtàn kangídì a dàgbò,
B’Óbìnrin kangídì a dìyálé,
Ìyálé tó bá kangídì ní í m’ètò àsè..!

Koríko wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́ digbó,
Ìrì wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́ d’òjò,
Ahéré di abà,
Abà dìlú ńlá
Omi sẹ́lẹ̀rú ṣe bẹ́ẹ̀ ó d’odò tí ń sàn tó ń s’aráyé láńfààní,
Ọmọ ìkókó ló pàpà di baba,
Aròbó àná ló dìyálé sọ́ọ̀dẹ̀!

Iṣẹ́ Akin ló sọ ọmọ Mákindé di àpèwááwò káàkiri ilẹ̀ yìí,
Gbogbo ìpínlè ló ń w’ọkọ Olúfúnkẹ́ bí i kó jẹ́ tiwọn,
Jákèjádò ilẹ̀ Yorùbá ni wón ń fẹ Ọmọ Ọlátúbọ̀sún dọ́kàn!

 

Sèyí Mákindé, Ìnáròbó lẹ́nu alátakò àná ti ṣe bẹ́ẹ̀ ó dọ̀gá ńlá!
Isẹ́ ribiribi tó f’Akin ṣe ló wú Òṣémàwé lórí,
Ó ṣe bẹ́ẹ̀ ó di JAGUNMÓLÚ l’Óǹdó ẹ̀gin,
Ọkọ Olúfúnnkẹ́ ti dolórí oko fún gbogbo wọn,
Ọmọ ‘Látúbọ̀sún ti sọ àwọn òpè dakúrẹtẹ̀ kalẹ̀.

Ẹ wọ̀tún, ẹ tún wòsì wò ná,
Ẹ wo ‘wájú kí ẹ tún wẹ̀yìn kún,
Ẹ wò ‘là kẹ́ ẹ tún wò ‘wọ̀ oòrùn,
Ẹ ṣíjú wo Gúúsù kí ẹ w’àríwá ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́,
Ẹ wo bó ṣe sọgbó dilé,
Ẹ wo bó ṣe sọ̀ ‘gbẹ́ dìgboro,
Ẹ rí i bó ṣe sọ gbogbo àkìtàn ilẹ̀ yìí dọjà tó ń tà wàràwàrà!

Ṣèyí kúrò láròbó,
Ọpọlọ pípé lọmọ Májọlágbé fi ń ṣiṣẹ́ ọba,
Ìbẹ̀rù Ọlọ́hun tó fi ń sìnlú ti pọ̀tá lẹ́numọ́,
Wọ́n ò sọ̀tẹ̀ mọ́,
Àní wọ́n ti gbáròyé tì!

A dúpẹ́ nípìnlẹ̀ Ọ̀yọ́,
A ò gbé aṣọ wa rán fónígbàjámọ̀,
A ò gbé irun orí fún kanlékanlé,
A ò bẹ fọganáísà pé kó báwa tún ìlẹ̀kùn wa ṣe!

Ọ̀bẹ kò ṣe é gé ‘gi
Àáké kò ṣe é hó’sàn
Àdá kò dùn ún fárí rárá
Olórí pípé la gbéṣẹ́ fún nìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́,
Abìwà pẹ̀lẹ́ bí orí adẹ́tù
Olúṣèyí Abíọ́dún ọmọ Mákindé
Wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́ nikán ń mọlé,
Pẹ̀lẹ́pùtù là á yọ’ṣẹ̀ lẹ́kù,
Máa ṣe wẹ́rẹ́ forí pípé tukọ̀ ìjọba ìpínlẹ̀ yìí nìsó,
Igbá oyin lo gbé, o ò gbé ‘gbá ata!
Mùmùràrà layé ń dẹ̀wá lọ́rùn.

Ṣèyí Mákindé JAGUNMÓLÚ,

Oyè á mọ́rí ooooo!

author avatar
eaglessightnews
Eaglessightnews is an online news paper that started December 2020. We promote human rights and support good governance. We update happenings around the world. We unveil the truth about breaking news. We promote good contents. Our focus is not self centered but to serve humanity.

Leave a Reply